Odun mewa ree ti moti’n reti ojo. Kosi ounje, kosi omi. Eye oke bi eye. Eku oke bi eku. Koda, kosi eye tabi eku mo. Gbogbo won ti wa ibo miran gba lo. Kii se wipe emi naa ofe wa igbi gba lo. Sugbon ina ati omi ni koje k’in ri ona lo. Tofi je wipe, ti mo rin si iwaji, maa tun ba araa mi ti mo’n ri pada bo wa sibi.
Ni ọdún púpọ̀ ṣeyìn, gbogbo ẹgbẹ́ mi ni wàán gbé ìyàwó. Ṣùgbọ́n, ṣe ẹni tí kò ní nkankan amà gbé ìyàwó ni? Mi oni ile, beesi ni mi oni ona. Aarin oja ni mo’n sun si. Gbogbo ara ilu ama fimi se yeye. Moni ogbon ni ori. Beesi ni, moni isan ni apa. Baba Ibu ni mo’n ba se ise. Awa ni a’nta omi fun gbogbo ilu. Awa naa ni a’n se akoso ojo riro. At omo odun mewa ni moti wa ni odo Baba naa. Oun ni omu mi sodo ni igba ti awon obi mise alaisi. Igba ti mo pe omo odun meji din l’ogun, moni anfani lati mu owo ti moti kojo lo fi se owo miran. Ṣùgbọ́n Baba ti di arugbo, nitori naa, mo ko owo naa fun baba ki ole ta owo omi tita re fun mi.
Awon ara ilu ofi tara-tara feran Baba Ibu. Oma’n fi ina jo oko oloko lati le je ki omi sun daada si odo re. Igba miran, oma’n fi iya ojo je eni ti koba gba ki Baba o da ina sun oko oun. Baba tun le ni ki ojo ro ni aro yawole. Osi tun le ni ki ojo dawo duro fun odiindin odun kan lati le fi da saria fun eni to oba laya lati wo oju re. Ṣùgbọ́n, ẹ̀mí orí Bàbá bí ènìyàn burúkú nítorí pé àwọn ìwà tí ó ń wù yìí kò pa ẹ̀mí lára. Igba ti oto ye mi ni igba ti mo ko owo fun Baba ti gbogbo oro omi ati ojo wa di temi. Akoko, mi ori eni keni ki owa ra omi. Osu melo kan koja, sibe sibe mi o ri eni wa bere omi. Agba ti da Baba to je wipe kole soro mo. Mi ori eni bi leere.
Ki baba to fi ise sile, gbogbo oko inu ilu ni oti da ina sun tan. Kosi ounje rara.
Igba toya, awon amu omi mi naa bere si’n gbe. Kosi oko ti mo le da ina sun lati fi pe omi wa sinu amu mi. Ojo ko, ko ro. Odun meji koja. Emi gan ori omi mumo. Baba ti se alaisi. Mi o ni olubasoro kankan. Awon ara ilu o bere omi lowo mi, sugbon mo mo wipe wan mu omi. Koyemi ibi ti won ti’n ri. Àsìkò yìí, òye kí n ti máa wọ ayika láti wá omidan tí mo fẹ́ fi ṣe ayá. Sugbon ni igba ti oungbe gbe mi de aye kan, mo bere sini ta awon amu ti mo ra ni odo baba. Amu ekini lo, amu ikeji lo, iketa, ikerin. Igba toya ni mo ta ile. Mowa di eni ti o’n su ni aarin oja.
Leyin odun marun lai si ounje tabi omi, awon ara ilu bere sini’n lo ni eyo kookan. Awa ti oku, atiirin bi igbale. A’n wo ofurufu boya ojo yi o ro. Sugbon ojo ko, ko ro. Kere kere, lara awa to seku, awon omiran naa tun lo kuro ninu ilu. Inu mi dun, nitori wipe, sisun oja dopin. Awon ti won kolo tunmo si wipe mo le ko wo ile ti won fi sile. Sugbon, wahala mi koiti de opin.
Fun ounje, emi ati awon ti oku, a’n je ewe ati igi. Fun omi, ama’n sa ara wa sinu orun, ki abaa le sun oogun sinu ife. Ti oogun naa bati po daada, ama’n daa sinu ero omii mi, ki iyo ati omi le pinya, ki ale mu omi toba wa’n le leyin ti aba setan. Sugbon, iru ise yi kole seese ti eniyan o ba po. Odun mejo ti koja, sibe sibe, ako ri ojo fun ojo kan bayi. Awa ti aku nile ko ju merin mo. Nise ni eru’n bami wipe awon naa maato so wipe odigba.
Leyin odun mewa, emi nikan loku. Moti gbiyanju lati lo, sugbon gbogbo ona ti mo ba dojuko, ina nla ati omi agbara ni mo ma’n ba pade nibe. Momo wipe iya ese Baba Ibu ni mo’n je yi, sugbon mi o le maje, nitori wipe emi ni mo ra owo naa lowo Baba Ibu. Gbogbo igi ni moti je tan. Oogun oju mi ko to fun omi sise mo. Motiirin gbeku. Sugbon mi ole fi ilu sile. Oseese wipe ojo ko ni ro ni ibi mo lailai. Emi ko le mo nitori wipe moti’n sunmo iku bayi. Mi ole dide. Mi ole rin kiri. Nitori naa, mofi egbe lele, kin sun die.
Omi ekan kan ni okoko kan simi leeke. Mo laju, mo woke. Omi ekan méjì, mẹ́ta, mẹ́rin, lóba’n kan sílẹ̀ láti ojú ọ̀run. Ojo ti de! Mo ń tẹ́ ọwọ́ láti lè mú omi sí ọ̀nà ofún gbigbé mi. Ojo ro ni aro gbale, omi ya si gbogbo ona. Amo, leyin wakati pupo, ojo naa ko da. Nse ni agbara e bere si’n ga. Oti ga de erukun ese. Leyin ojo meji, oti ga de itan. Mi o ri orun sun mo.
Ti ojo naa koba da, yi o di odo, odo naa yi osi gbe mi lo. Abi gbogbo ojo ti ko wa ni odun mewa lofe wa ni eekan naa yi? Ti yi o ba fi odun mewa ro, ko le pe ojo mewa ti yi o ti pa mi. A ṣe wípé ẹ̀sẹ̀ Baba Ibù tí kọba mi patapata niyẹn.
Janet Olobadola
Janet Olobadola is a Nigerian poet journaling her experiences of loss and grief. She writes in both English and her native Yoruba language, and her work has been published in Kalahari Review and the defunct Okadabooks. She has also read her work at many literary festivals.
