Omijé Ojú Ọ̀run (Yorùbá Poem)

You are currently viewing Omijé Ojú Ọ̀run (Yorùbá Poem)
Photo by Alex Dukhanov on Unsplash

Ojú ọ̀run ṣú biri biri, atẹ́gùn nlá mi ilẹ̀ mìtìtì

Ará ọjà’n palẹ̀ mọ́, ẹran oko’n wá ibòji kiri

Ṣé òjò yí ó rọ̀ bí, tàbí òjò kò ní rọ̀?

Òjò kọ́ o, ẹ̀yin ará ilé

Omi ẹkún ojú mi ni ó’n lérí làti dà wálẹ̀


Ìpọ́njú ò kí’n mú oúnjẹ lọ lẹ́nu

Ìbànújẹ́ ò mọ adùn, bẹ́ẹ̀ sì ni kò mọ jẹ́ kájọ jó

Ẹni ọbá gbà ní ìyàwó, kò sí ẹni tí yí ó ki pẹ̀lẹ́

Ẹni ikú ṣe ìrẹ́jẹ fún, ṣé yí ó wa yọ àdá sí Elédùmarè ni?

Omi ẹkún ojú mi l’ón bẹ̀bẹ̀ fún òmìnira ò


Ní ọjọ́ kíní ànọ́, gbogbo ayé báwa yọ́ wípé ati di ọlọ́lá

Ọlá náà dé ní tòótọ́, sùgbọ́n àpò alápò ló bọ́sí

Epo’n dàmọ́ omi òkun, àìsàn’n dàmú gbogbo ará ìlú

Ẹja inú omi tidi màjèlé, ìyáa tèmi nìkan kọ́ ló jẹ níbẹ̀ o

Omi ẹkún ojú gbogbo wa ni ò’n fẹ́ bíbí báyi


Ilé ayé ti wà kí ató wá

Àmọ́ owó àti ọrọ̀ kò jẹ́ kí alágbára náání ilẹ̀ tí ó’n tẹ̀

Ojú ọ̀run ṣú biri biri, atẹ́gùn nlá mi ilẹ̀ mìtìtì

Àṣé bí ìbànújẹ́ ṣe gba ọkàn ènìyàn, ni óṣe’n gba ọkàn ayé náà 

Ni ìgbà tí ìjì náà bádé, yí ó kó ilé, ọ̀nà, àti gbogbo wa pẹ̀lú omijé wàrà wàrà

Leah Ojúọlápé Adéyẹyè

Leah Ojúọlápé Adéyẹyè

Leah Ojúọlápé Adéyẹyè is a story enthusiast who enjoys telling them to little children, especially her grandkids, with whom she often lay side by side on raffia or rubber mats at night, staring into the sky and counting stars, telling stories about what went on in each one. She was a finalist for Faber Children’s FAB Prize in 2023.